Matthew 7:16-20

16Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, 20Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.

Copyright information for YorBMYO